Native Bible

Romans 10:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí bí wọn kò tí mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọ́n si ń wá ọ̀nà láti gbé òdodo ara wọn kalẹ̀, wọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run.

Romans 10:3 in English

Romans 10:3 · Berean Standard Bible

Because they were ignorant of God’s righteousness and sought to establish their own, they did not submit to God’s righteousness.

Context

1Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ìfẹ́ ọkàn àti àdúrà mi sí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn Israẹli ni kí wọ́n le ní ìgbàlà. 2Nítorí mo gba ẹ̀rí wọn jẹ́ wí pé, wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run, ṣùgbọ́n kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀. 3Nítorí bí wọn kò tí mọ òdodo Ọlọ́run, tí wọ́n si ń wá ọ̀nà láti gbé òdodo ara wọn kalẹ̀, wọn kò tẹríba fún òdodo Ọlọ́run. 4Nítorí Kristi ni òpin òfin sí òdodo fún olúkúlùkù ẹni tí ó gbà á gbọ́. 5Mose ṣá kọ èyí nípa òdodo tí í ṣe ti òfin pé, “Ẹni tí ó ba ṣe, yóò yè nípa wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.