Native Bible

Romans 1:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi kò tijú ìyìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú.

Romans 1:16 in English

Romans 1:16 · Berean Standard Bible

I am not ashamed of the gospel, because it is the power of God for salvation to everyone who believes, first to the Jew, then to the Greek.

Context

14Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Giriki àti sí àwọn aláìgbédè tí kì í ṣe Giriki, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aṣiwèrè. 15Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìnrere Ọlọ́run sí i yín. 16Èmi kò tijú ìyìnrere Jesu, nítorí agbára Ọlọ́run ní ín ṣe láti gba gbogbo àwọn tí ó bá gbàgbọ́ là, ọ̀rọ̀ yìí ni a kọ́kọ́ wàásù sí àwọn Júù nìkan, ṣùgbọ́n nísinsin yìí fún àwọn Helleni pẹ̀lú. 17Nítorí nínú ìyìnrere ni òdodo Ọlọ́run ti farahàn, òdodo Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ nínú Ìwé Mímọ́ pé, “Olódodo yóò yè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀.” 18Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.