Romu 1:13
Romans 1:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrín yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní láàrín àwọn aláìkọlà yòókù.
Romans 1:13 in English
Romans 1:13 · Berean Standard Bible
I do not want you to be unaware, brothers, how often I planned to come to you (but have been prevented from visiting * until now), in order that I might have a harvest among you, just as I have had among the other Gentiles.
Context
11Nítorí èmi ń fẹ́ gidigidi láti tọ̀ yín wá, kí èmi lè fún yín ní ẹ̀bùn ẹ̀mí díẹ̀, kí a bá a le sọ yín di alágbára nínú Olúwa, 12èyí nì ni pé, kí a lè jẹ́ ìwúrí fún ara wa nípa ìgbàgbọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. 13Mo fẹ́ kí ẹ mọ èyí, ẹ̀yin ará mi, pé mo ti gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ̀ yín wá (ṣùgbọ́n ìdíwọ́ wà fún mi), kí èmi ki ó lè jèrè ọkàn díẹ̀ láàrín yín, gẹ́gẹ́ bí mo ti ní láàrín àwọn aláìkọlà yòókù. 14Nítorí mo jẹ́ ajigbèsè sí Giriki àti sí àwọn aláìgbédè tí kì í ṣe Giriki, sí àwọn ọlọ́gbọ́n àti sí àwọn aṣiwèrè. 15Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe ń làkàkà láti wá sí Romu àti láti fi gbogbo agbára mi wàásù ìyìnrere Ọlọ́run sí i yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.