Native Bible

Revelation 9:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn.

Revelation 9:4 in English

Revelation 9:4 · Berean Standard Bible

They were told not to harm the grass of the earth or any plant or tree, but only those who did not have the seal of God on their foreheads.

Context

2Ó sì ṣí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èéfín ìléru ńlá, oòrùn àti ojú sánmọ̀ sì ṣókùnkùn nítorí èéfín ihò náà. 3Àwọn eṣú sì jáde ti inú èéfín náà wá sórí ilẹ̀, a sì fi agbára fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbára àkéekèe ilẹ̀. 4A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn. 5A sì pàṣẹ fún wọn pé, kí wọn má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n kí a dá wọn ni oró ni oṣù márùn-ún, oró wọn sì dàbí oró àkéekèe, nígbà tí o bá ta ènìyàn. 6Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn yóò sì máa wá ikú, wọn kì yóò sì rí i; wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ikú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.