Native Bible

Revelation 9:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Angẹli karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀, mo sì rí, ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá, a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un.

Revelation 9:1 in English

Revelation 9:1 · Berean Standard Bible

Then the fifth angel sounded his trumpet, and I saw a star that had fallen from heaven to earth, and it was given the key to the pit of the Abyss.

Context

1Angẹli karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀, mo sì rí, ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá, a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un. 2Ó sì ṣí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èéfín ìléru ńlá, oòrùn àti ojú sánmọ̀ sì ṣókùnkùn nítorí èéfín ihò náà. 3Àwọn eṣú sì jáde ti inú èéfín náà wá sórí ilẹ̀, a sì fi agbára fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbára àkéekèe ilẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.