Ìfihàn 8:9
Revelation 8:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àti ìdámẹ́ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú Òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́.
Revelation 8:9 in English
Revelation 8:9 · Berean Standard Bible
a third of the living creatures in the sea died, and a third of the ships were destroyed.
Context
7Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀, Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ́ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ́ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jóná. 8Angẹli kejì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òkè ńlá tí ń jóná, sínú Òkun: ìdámẹ́ta Òkun si di ẹ̀jẹ̀; 9àti ìdámẹ́ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú Òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́. 10Angẹli kẹta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ́ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi. 11A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ, ìdámẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.