Native Bible

Revelation 8:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Angẹli kẹta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ́ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi.

Revelation 8:10 in English

Revelation 8:10 · Berean Standard Bible

Then the third angel sounded his trumpet, and a great star burning like a torch fell from heaven and landed on a third of the rivers and on the springs of water.

Context

8Angẹli kejì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òkè ńlá tí ń jóná, sínú Òkun: ìdámẹ́ta Òkun si di ẹ̀jẹ̀; 9àti ìdámẹ́ta àwọn ẹ̀dá tí ń bẹ nínú Òkun tí ó ni ẹ̀mí sì kú; àti ìdámẹ́ta àwọn ọkọ̀ si bàjẹ́. 10Angẹli kẹta sì fún ìpè tirẹ̀, ìràwọ̀ ńlá kan tí ń jó bí fìtílà sì bọ́ láti ọ̀run wá, ó sì bọ́ sórí ìdámẹ́ta àwọn odò ṣíṣàn, àti sórí àwọn orísun omi. 11A sì ń pe orúkọ ìràwọ̀ náà ní Iwọ, ìdámẹ́ta àwọn omi sì di iwọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì tí ipa àwọn omi náà kú, nítorí tí a sọ wọn di kíkorò. 12Angẹli kẹrin sì fún ìpè tirẹ̀, a sì kọlu ìdámẹ́ta oòrùn, àti ìdámẹ́ta òṣùpá, àti ìdámẹ́ta àwọn ìràwọ̀, ki ìdámẹ́ta wọn lè ṣókùnkùn, kí ọjọ́ má ṣe mọ́lẹ̀ fún ìdámẹ́ta rẹ̀, àti òru bákan náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.