Ìfihàn 8:6
Revelation 8:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn angẹli méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn.
Revelation 8:6 in English
Revelation 8:6 · Berean Standard Bible
And the seven angels with the seven trumpets prepared to sound them.
Context
4Àti èéfín tùràrí náà pẹ̀lú àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́ sì gòkè lọ síwájú Ọlọ́run láti ọwọ́ angẹli náà wá. 5Angẹli náà sì mú àwo tùràrí náà, ó sì fi iná orí pẹpẹ kùn ún, ó sì dà á sórí ilẹ̀ ayé, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, mọ̀nàmọ́ná sì kọ, àti ilẹ̀-rírì. 6Àwọn angẹli méje náà tí wọn ni ìpè méje sì múra láti fún wọn. 7Èkínní sì fọn ìpè tirẹ̀, Yìnyín àti iná, tí o dàpọ̀ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀, sì jáde, a sì dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé: ìdámẹ́ta ilẹ̀ ayé si jóná, ìdámẹ́ta àwọn igi sì jóná, àti gbogbo koríko tútù sì jóná. 8Angẹli kejì si fún ìpè tirẹ̀, a sì sọ ohun kan, bí òkè ńlá tí ń jóná, sínú Òkun: ìdámẹ́ta Òkun si di ẹ̀jẹ̀;
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.