Ìfihàn 5:7
Revelation 5:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì wá, o sì gbà á ìwé náà ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà.
Revelation 5:7 in English
Revelation 5:7 · Berean Standard Bible
And He came and took the scroll from the right hand of the One seated on the throne.
Context
5Ọ̀kan nínú àwọn àgbà náà sì wí fún mi pé, “Má ṣe sọkún: kíyèsi i, kìnnìún ẹ̀yà Juda, Gbòǹgbò Dafidi, tí borí láti ṣí ìwé náà, àti láti tú èdìdì rẹ̀ méjèèje.” 6Mo sì rí Ọ̀dọ́-Àgùntàn ni àárín ìtẹ́ náà, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti ni àárín àwọn àgbà náà, Ọ̀dọ́-àgùntàn kan dúró bí èyí tí a ti pa, ó ní ìwo méje àti ojú méje, tí o jẹ́ Ẹ̀mí méje tí Ọlọ́run, tí a rán jáde lọ sì orí ilẹ̀ ayé gbogbo. 7Ó sì wá, o sì gbà á ìwé náà ni ọwọ́ ọ̀tún ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ náà. 8Nígbà tí ó sì gba ìwé náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, àti àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà wólẹ̀ níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn náà, olúkúlùkù wọn mú ohun èlò orin olókùn kan lọ́wọ́, àti ago wúrà tí ó kún fún tùràrí tí i ṣe àdúrà àwọn ènìyàn mímọ́. 9Wọn sì ń kọ orin tuntun kan, wí pé:
“Ìwọ ní o yẹ láti gba ìwé náà,
àti láti ṣí èdìdì rẹ̀:
nítorí tí a tí pa ọ,
ìwọ sì tí fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe ìràpadà ènìyàn sí Ọlọ́run láti inú ẹ̀yà gbogbo,
àti èdè gbogbo, àti inú ènìyàn gbogbo, àti orílẹ̀-èdè gbogbo wá.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.