Native Bible

Revelation 4:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé.

Revelation 4:9 in English

Revelation 4:9 · Berean Standard Bible

And whenever the living creatures give glory, honor, and thanks to the One seated on the throne who lives forever and ever,

Context

7Ẹ̀dá kìn-ín-ní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kejì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹrin sì dàbí idì tí ń fò. 8Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn àti lóru, láti wí pé: “ ‘Mímọ́, mímọ́, mímọ́, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,’ tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!” 9Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé. 10Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà yóò sì wólẹ̀ níwájú ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, wọn yóò sì tẹríba fún ẹni tí ń bẹ láààyè láé àti láéláé, wọn yóò sì fi adé wọn lélẹ̀ níwájú ìtẹ́ náà, wí pé: 11“Olúwa àti Ọlọ́run, ìwọ ni o yẹ, láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni o dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ inú rẹ̀ ni wọn fi wà tí a sì dá wọn.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.