Ìfihàn 4:7
Revelation 4:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ̀dá kìn-ín-ní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kejì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹrin sì dàbí idì tí ń fò.
Revelation 4:7 in English
Revelation 4:7 · Berean Standard Bible
The first living creature was like a lion, the second like a calf, the third had a face like a man, and the fourth was like an eagle in flight.
Context
5Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni ìró mọ̀nàmọ́ná àti ohùn àti àrá ti jáde wá: níwájú ìtẹ́ náà ni fìtílà iná méje sì ń tàn, èyí tí ń ṣe Ẹ̀mí méje ti Ọlọ́run. 6Àti láti ibi ìtẹ́ náà ni òkun bi dígí wà tí o dàbí kristali.
Àti yí ìtẹ́ náà ká ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ni ẹ̀dá alààyè mẹ́rin tí ó kún fún ojú níwájú àti lẹ́yìn wọn. 7Ẹ̀dá kìn-ín-ní sì dàbí kìnnìún, ẹ̀dá kejì si dàbí ọmọ màlúù, ẹ̀dá kẹta sì ni ojú bi ti ènìyàn, ẹ̀dá kẹrin sì dàbí idì tí ń fò. 8Àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, tí olúkúlùkù wọn ni ìyẹ́ mẹ́fà, kún fún ojú yíká ara àti nínú; wọn kò sì sinmi lọ́sàn àti lóru, láti wí pé:
“ ‘Mímọ́, mímọ́, mímọ́,
Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,’
tí ó ti wà, tí ó sì ń bẹ, tí ó sì ń bọ̀ wá!” 9Nígbà tí àwọn ẹ̀dá alààyè náà bá sì fi ògo àti ọlá, àti ọpẹ́ fún ẹni tí o jókòó lórí ìtẹ́, tí o ń bẹ láààyè láé àti láéláé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.