Native Bible

Revelation 3:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀.

Revelation 3:5 in English

Revelation 3:5 · Berean Standard Bible

Like them, he who overcomes will be dressed in white. And I will never blot out * his name from the Book of Life, but I will confess his name before My Father and His angels.

Context

3Nítorí náà rántí bí ìwọ ti gbà, àti bí ìwọ ti gbọ́, kí o sì pa á mọ́, kí o sì ronúpìwàdà. Ǹjẹ́, bí ìwọ kò ba ṣọ́ra, èmi yóò dé sí ọ bí olè, ìwọ kì yóò sì mọ́ wákàtí tí èmi yóò dé sí ọ. 4Ìwọ ní orúkọ díẹ̀ ní Sardi, tí kò fi aṣọ wọn yí èérí; wọn yóò sì máa ba mi rìn ní aṣọ funfun: nítorí wọ́n yẹ. 5Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, òun náà ni a ó fi aṣọ funfun wọ̀; èmi kì yóò pa orúkọ rẹ̀ kúrò nínú ìwé ìyè, ṣùgbọ́n èmi yóò jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀ níwájú Baba mi, àti níwájú àwọn angẹli rẹ̀. 6Ẹni tí ó ba létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. 7“Àti sí angẹli Ìjọ ni Filadelfia kọ̀wé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó jẹ́ mímọ́ náà wí, ẹni tí ó ṣe olóòtítọ́, ẹni tí ó ní kọ́kọ́rọ́ Dafidi, ẹni tí ó ṣí, tí kò sí ẹni tí yóò tì; ẹni tí o sì tì, tí kò sì ẹni tí yóò ṣí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.