Ìfihàn 3:14
Revelation 3:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run.
Revelation 3:14 in English
Revelation 3:14 · Berean Standard Bible
To the angel of the church in Laodicea write: These are the words of the Amen, the faithful and true Witness, the Originator * of God’s creation.
Context
12Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́, èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi. 13Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. 14“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé.
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run. 15Èmi mọ̀ iṣẹ́ rẹ, pé ìwọ kò gbóná bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò tútù: èmi ìbá fẹ́ pé kí ìwọ kúkú tutù, tàbí kí ìwọ kúkú gbóná. 16Ǹjẹ́ nítorí tí ìwọ lọ wọ́ọ́rọ́, tí o kò si gbóná, bẹ́ẹ̀ ni tí o kò tutù, èmi yóò pọ̀ ọ́ jáde kúrò ni ẹnu mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.