Ìfihàn 3:12
Revelation 3:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́, èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi.
Revelation 3:12 in English
Revelation 3:12 · Berean Standard Bible
The one who overcomes I will make a pillar in the temple of My God, and he will never again leave it. Upon him I will write the name of My God, and the name of the city of My God (the new Jerusalem that comes down out of heaven from My God), and My new name.
Context
10Nítorí tí ìwọ tí pa ọ̀rọ̀ sùúrù mi mọ́, èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, tí ń bọ̀ wá dé bá gbogbo ayé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò. 11Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán, di èyí ti ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnikẹ́ni má ṣe gba adé rẹ. 12Ẹni tí ó ba ṣẹ́gun, òun ni èmi ó fi ṣe ọ̀wọ́n nínú tẹmpili Ọlọ́run mi, òun kì yóò sì jáde kúrò níbẹ̀ mọ́, èmi ó sì kọ orúkọ Ọlọ́run mi sí i lára, àti orúkọ ìlú Ọlọ́run mi, tí i ṣe Jerusalẹmu tuntun, tí ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run mi wá: àti orúkọ tuntun ti èmi tìkára mi. 13Ẹni tí ó bá ní etí, kí ó gbọ́ ohun ti Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. 14“Àti sí angẹli ìjọ ní Laodikea kọ̀wé.
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ń jẹ́ Àmín wí, ẹlẹ́rìí olódodo àti olóòtítọ́, olórí ìṣẹ̀dá Ọlọ́run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.