Native Bible

Revelation 22:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi.

Revelation 22:8 in English

Revelation 22:8 · Berean Standard Bible

And I am John, who heard and saw these things. And when I had heard and seen them, I fell down to worship at the feet of the angel who had shown me these things.

Context

6Ó sì wí fún mi pé, “Òdodo àti òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: Olúwa Ọlọ́run ẹ̀mí àwọn wòlíì ni ó sì ran angẹli rẹ̀ láti fi ohun tí ó ní láti ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí hàn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.” 7“Kíyèsi i, èmi ń bọ̀ kánkán! Ìbùkún ni fún ẹni tí ń pa ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé yìí mọ́!” 8Èmi, Johanu, ni ẹni tí ó gbọ́ tí ó sì ri nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí mo sì gbọ́ tí mo sì rí, mo wólẹ̀ láti foríbalẹ̀ níwájú ẹsẹ̀ angẹli náà, tí o fi nǹkan wọ̀nyí hàn mi. 9Nígbà náà ni ó wí fún mi pé, “Wó ò, má ṣe bẹ́ẹ̀, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ wòlíì, àti ti àwọn tí ń pa ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí mọ́. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run!” 10Ó sì wí fún mi pé, “Má ṣe fi èdìdì di ọ̀rọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ tí inú ìwé yìí, nítorí ìgbà kù sí dẹ̀dẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.