Native Bible

Revelation 22:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ní àárín ìgboro rẹ̀, àti níhà èkínní kejì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so onírúurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà.

Revelation 22:2 in English

Revelation 22:2 · Berean Standard Bible

down the middle of the main street of the city. On either side of the river stood a tree of life, bearing twelve kinds of fruit and yielding a fresh crop for each month. And the leaves of the tree are for the healing of the nations.

Context

1Ó sì fi odò omi ìyè kan hàn mi, tí ó mọ́ bí kirisitali, tí ń tí ibi ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-Àgùntàn jáde wá, 2ní àárín ìgboro rẹ̀, àti níhà èkínní kejì odò náà, ni igi ìyè gbé wà, tí o máa ń so onírúurú èso méjìlá, a sì máa so èso rẹ̀ ni oṣooṣù ewé igi náà sí wà fún mímú àwọn orílẹ̀-èdè láradà. 3Ègún kì yóò sì ṣí mọ: ìtẹ́ Ọlọ́run àti tí Ọ̀dọ́-àgùntàn ni yóò sì máa wà níbẹ̀; àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò sì máa sìn ín. 4Wọ́n ó si máa rí ojú rẹ̀; orúkọ rẹ̀ yóò si máa wà ni iwájú orí wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.