Native Bible

Revelation 21:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i, nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀.

Revelation 21:23 in English

Revelation 21:23 · Berean Standard Bible

And the city has no need of sun or moon to shine on it, because the glory of God illuminates the city, and the Lamb is its lamp.

Context

21Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ perli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán. 22Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn. 23Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i, nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀. 24Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀. 25A kì yóò sì ṣé àwọn ẹnu ibodè rẹ̀ rárá ní ọ̀sán: nítorí ki yóò si òru níbẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.