Native Bible

Revelation 21:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn.

Revelation 21:22 in English

Revelation 21:22 · Berean Standard Bible

But I saw no temple in the city, because the Lord God Almighty and the Lamb are its temple.

Context

20ẹ̀karùnún, sardoniki; ẹ̀kẹfà, kaneliani; èkeje, krisoliti; ẹ̀kẹjọ, berili; ẹ̀kẹsànán, topasi; ẹ̀kẹwàá, krisoprasu; ẹ̀kọkànlá, jakiniti; èkejìlá, ametisiti. 21Ẹnu ibodè méjèèjìlá jẹ́ perli méjìlá: olúkúlùkù ẹnu ibodè jẹ́ peali kan; ọ̀nà ìgboro ìlú náà sì jẹ́ kìkì wúrà, ó dàbí dígí dídán. 22Èmi kò sì ri tẹmpili nínú rẹ̀, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè ni tẹmpili rẹ̀, àti Ọ̀dọ́-àgùntàn. 23Ìlú náà kò sì ní oòrùn, tàbí òṣùpá, láti máa tan ìmọ́lẹ̀ sí i, nítorí pé ògo Ọlọ́run ni ó ń tàn ìmọ́lẹ̀ sí i, Ọ̀dọ́-àgùntàn sì ni fìtílà rẹ̀. 24Àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì máa rìn nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ọba ayé sì ń mú ògo wọn wá sínú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.