Ìfihàn 21:1
Revelation 21:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan, nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; Òkun kò sì ṣí mọ́.
Revelation 21:1 in English
Revelation 21:1 · Berean Standard Bible
Then I saw a new heaven and a new earth,* for the first heaven and earth had passed away, and the sea was no more.
Context
1Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ayé tuntun kan, nítorí pé ọ̀run ti ìṣáájú àti ayé ìṣáájú ti kọjá lọ; Òkun kò sì ṣí mọ́. 2Mo sì rí ìlú mímọ́, Jerusalẹmu tuntun ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, tí a ti múra sílẹ̀ bí ìyàwó tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀. 3Mo sì gbọ́ ohùn ńlá kan láti orí ìtẹ́ náà wá, ń wí pé, “Kíyèsi i, àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn, òun ó sì máa bá wọn gbé, wọn ó sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀, àti Ọlọ́run tìkára rẹ̀ yóò wà pẹ̀lú wọn, yóò sì máa jẹ́ Ọlọ́run wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.