Ìfihàn 2:19
Revelation 2:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí ìṣáájú lọ.
Revelation 2:19 in English
Revelation 2:19 · Berean Standard Bible
I know your deeds—your love, your faith, your service, your perseverance—and your latter deeds are greater than your first.
Context
17Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi manna tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á. 18“Àti sí angẹli ìjọ ní Tiatira kọ̀wé.
Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára. 19Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí ìṣáájú lọ. 20Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sí ọ, nítorí tí ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún obìnrin Jesebeli tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sì òrìṣà. 21Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.