Ìfihàn 16:7
Revelation 16:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì gbọ́ ti pẹpẹ ń ké wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè, òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.”
Revelation 16:7 in English
Revelation 16:7 · Berean Standard Bible
And I heard the altar reply: “Yes, Lord God Almighty, true and just are Your judgments.”
Context
5Mo sì gbọ́ angẹli tí ó n wí pé:
“Olódodo ni ìwọ ninu gbogbo ìdájọ́ wọ̀nyí,
ìwọ ẹni tí ó n bẹ àti tí ó tí wa, Ẹni Mímọ́
nítorí tí ìwọ ṣe ìdájọ́ bẹ́ẹ̀. 6Nítorí tí wọ́n ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ àti ti àwọn wòlíì sílẹ̀,
ìwọ sì fi ẹ̀jẹ̀ fún wọn mu; èyí yìí ní ó yẹ wọ́n.” 7Mo sì gbọ́ ti pẹpẹ ń ké wí pé:
“Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa Ọlọ́run Olódùmarè,
òtítọ́ àti òdodo ní ìdájọ́ rẹ.” 8Ẹ̀kẹrin sì tú ago tirẹ̀ sórí oòrùn; a sì yọ̀ǹda fún un láti fi iná jó ènìyàn lára. 9A sì fi ooru ńlá jó àwọn ènìyàn lára, wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run, ẹni tí ó ní agbára lórí ìyọnu wọ̀nyí: wọn kò sì ronúpìwàdà láti fi ògo fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.