Saamu 93
Psalms 93 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
1Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
kò sì le è yí. 2Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
ìwọ wà títí ayérayé. 3A ti gbé òkun sókè, Olúwa,
òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
òkun ti gbé rírú omi wọn sókè. 4Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
ó ni ògo ju òkun rírú lọ
Olúwa ga ní ògo. 5Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.