Native Bible

Psalms 92:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi; ìparun sí àwọn ènìyàn búburú tí ó dìde sí mi.

Psalms 92:11 in English

Psalms 92:11 · Berean Standard Bible

My eyes see the downfall of my enemies; my ears hear the wailing of my wicked foes.*

Context

9Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ, Olúwa, nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé; gbogbo àwọn olùṣe búburú ni a ó fọ́nká. 10Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó; òróró dídára ni a dà sí mi ní orí. 11Ojú mi ti rí ìṣubú àwọn ọ̀tá mi; ìparun sí àwọn ènìyàn búburú tí ó dìde sí mi. 12Olódodo yóò gbèrú bí i igi ọ̀pẹ, wọn yóò dàgbà bí i igi kedari Lebanoni, 13tí a gbìn sí ilé Olúwa, Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.