Native Bible

Psalms 9:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo; yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo.

Psalms 9:8 in English

Psalms 9:8 · Berean Standard Bible

He judges the world with justice; He governs the people with equity.

Context

6Ìparun àìlópin ti borí àwọn ọ̀tá, ìwọ ti fa àwọn ìlú wọn tu; àní ìrántí wọn sì ti ṣègbé. 7Olúwa jẹ ọba títí láé; ó ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ fún ìdájọ́. 8Òun yóò sì ṣe ìdájọ́ ayé ní òdodo; yóò ṣe àkóso ènìyàn pẹ̀lú òdodo. 9Olúwa ni ààbò fún àwọn tí a ni lára, ibi ìsádi ní àkókò ìpọ́njú. 10Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò gbẹ́kẹ̀lé ọ, nítorí, Olúwa, kò kọ àwọn tó ń wá a sílẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.