Saamu 89:9
Psalms 89:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìwọ ń darí ríru omi Òkun; nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
Psalms 89:9 in English
Psalms 89:9 · Berean Standard Bible
You rule the raging sea; when its waves mount up, You still them.
Context
7Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;
ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká. 8Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ
ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká. 9Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;
nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́. 10Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ
bí ẹni tí a pa;
ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ
tú àwọn ọ̀tá rẹ ká. 11Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:
ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀:
ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.