Native Bible

Psalms 8:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ, láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́.

Psalms 8:2 in English

Psalms 8:2 · Berean Standard Bible

From the mouths of children and infants You have ordained praise * on account of Your adversaries, to silence the enemy and avenger.

Context

1Olúwa, Olúwa wa, orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé! Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga ju àwọn ọ̀run lọ. 2Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ, láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́. 3Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ, iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti ìràwọ̀, tí ìwọ tí gbé kalẹ̀, 4kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀, àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.