Native Bible

Psalms 77:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run, nígbà tí àwọn omi rí ọ, ẹ̀rù bà wọ́n, nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀.

Psalms 77:16 in English

Psalms 77:16 · Berean Standard Bible

The waters saw You, O God; the waters saw You and swirled; even the depths were shaken.

Context

14Ìwọ ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìyanu; ìwọ fi agbára rẹ hàn nínú àwọn ènìyàn. 15Pẹ̀lú ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ ra àwọn ènìyàn padà, àwọn ọmọ Jakọbu àti Josẹfu. Sela. 16Nígbà tí àwọn omi rí Ọlọ́run, nígbà tí àwọn omi rí ọ, ẹ̀rù bà wọ́n, nítòótọ́ ara ibú kò balẹ̀. 17Àwọn ojú ọ̀run tú omi sílẹ̀, àwọsánmọ̀ fi àrá dáhùn; ọfà rẹ̀ ń tàn sẹ́yìn àti síwájú. 18Àrá rẹ̀ ni a gbọ́ nínú ìjì, ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ sí gbogbo ayé; ayé bẹ̀rù, wọ́n sì wárìrì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.