Saamu 74:20
Psalms 74:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bojú wo májẹ̀mú rẹ, nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà.
Psalms 74:20 in English
Psalms 74:20 · Berean Standard Bible
Consider Your covenant, for haunts of violence fill the dark places of the land.
Context
18Rántí bí àwọn ọ̀tá ń kẹ́gàn rẹ, Olúwa
bí àwọn aṣiwèrè ènìyàn ti ń ba orúkọ rẹ jẹ́. 19Má ṣe fi ẹ̀mí àdàbà rẹ fún ẹranko igbó búburú;
má ṣe gbàgbé ẹ̀mí àwọn ènìyàn rẹ tí a ń pọ́n lójú títí láé. 20Bojú wo májẹ̀mú rẹ,
nítorí ibi òkùnkùn ayé kún fún ibùgbé ìkà. 21Má ṣe jẹ́ kí àwọn aninilára padà sẹ́yìn nínú ìtìjú
jẹ́ kí àwọn aláìní àti tálákà yin orúkọ rẹ. 22Dìde, Ọlọ́run, gba ẹjọ́ ara rẹ rò;
rántí bí àwọn aṣiwèrè ti ń kẹ́gàn rẹ ní gbogbo ọjọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.