Native Bible

Psalms 71:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú, kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù bo àwọn tí ń wá ìpalára mi.

Psalms 71:13 in English

Psalms 71:13 · Berean Standard Bible

May the accusers of my soul be ashamed and consumed; may those who seek my harm be covered with scorn and disgrace.

Context

11Wọ́n wí pé, “Ọlọ́run ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀; lépa rẹ̀ kí ẹ sì mu, nítorí kò sí ẹni tí yóò gbà á.” 12Má ṣe jìnnà sí mi, Ọlọ́run; wa kánkán, Ọlọ́run mi, láti ràn mí lọ́wọ́. 13Jẹ́ kí wọn kí ó dààmú, kí a sì run àwọn tí ń ṣe ọ̀tá ọkàn mi kí a sì fi ẹ̀gàn àti àbùkù bo àwọn tí ń wá ìpalára mi. 14Ṣùgbọ́n ní tèmi, ìgbà gbogbo ní ìrètí mi; èmi ó yìn ọ́ síwájú àti síwájú sí i. 15Ẹnu mi yóò sọ nípa ti òdodo rẹ, ti ìgbàlà rẹ, ni gbogbo ọjọ́, lóòtítọ́, èmi kò mọ iye rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.