Saamu 70:3
Psalms 70:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!”
Psalms 70:3 in English
Psalms 70:3 · Berean Standard Bible
May those who say, “Aha, aha!” retreat because of their shame.
Context
1Yára, Ọlọ́run, láti gbà mí là,
Olúwa, wá kánkán láti ràn mí lọ́wọ́. 2Kí àwọn tí ń wá ọkàn mi
kí a dójútì wọ́n, kí wọn sì dààmú;
kí àwọn tó ń wá ìparun mi
yí ẹ̀yìn padà nínú ìtìjú. 3Kí a pa wọ́n ní ẹ̀yìn dà fún èrè
ìtìjú àwọn tí ń wí pé, “Háà! Háà!” 4Ṣùgbọ́n kí àwọn tí ó ń wá ọ ó máa yọ̀
kí inú wọn kí ó sì máa dùn nípa rẹ,
kí àwọn tí ó ń fẹ́ ìgbàlà rẹ máa wí pé,
“Jẹ́ kí a gbé Ọlọ́run ga!” 5Ṣùgbọ́n mo jẹ́ òtòṣì àti aláìní;
wa kánkán sí ọ̀dọ̀ mi, Ọlọ́run.
Ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ àti olùdáǹdè mi;
Olúwa, má ṣe dúró pẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.