Saamu 66:8
Psalms 66:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn, jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀;
Psalms 66:8 in English
Psalms 66:8 · Berean Standard Bible
Bless our God, O peoples; let the sound of His praise be heard.
Context
6Ó yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,
wọ́n fi ẹsẹ̀ rin inú omi kọjá,
níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú rẹ̀. 7Ó ń jẹ ọba títí láé nípa agbára rẹ̀,
ojú rẹ̀ ń wo orílẹ̀-èdè
kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela. 8Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,
jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohùn ìyìn rẹ̀; 9Ó ti dá ààbò bo ẹ̀mí wa,
kò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí ó yẹ̀. 10Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, dán wa wò;
ìwọ dán wa bí a tí ń dán fàdákà wò.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.