Native Bible

Psalms 55:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́, ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ, ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.

Psalms 55:21 in English

Psalms 55:21 · Berean Standard Bible

His speech is smooth as butter, but war is in his heart. His words are softer than oil, yet they are swords unsheathed.

Context

19Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì Sela, nítorí tí wọn kò ní àyípadà, tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run. 20Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀; ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́. 21Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́, ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀; ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ, ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn. 22Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa yóò sì mú ọ dúró; òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú. 23Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi wá sí ihò ìparun; àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn, kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn. Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.