Native Bible

Psalms 55:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi, ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi,

Psalms 55:13 in English

Psalms 55:13 · Berean Standard Bible

But it is you, a man like myself, my companion and close friend.

Context

11Ìwà búburú ń bẹ ní àárín rẹ̀; ẹ̀tàn àti èké kò kúrò ní ìgboro rẹ̀. 12Tí ọ̀tá bá tàbùkù mi, èmi yóò fi ara mọ́ ọn; tí ọ̀tá bá gbé ara rẹ̀ ga sí mi, èmi ìbá sá pamọ́ fún un. 13Ṣùgbọ́n tí ó bá ṣe ìwọ, ọkùnrin bí ẹgbẹ́ mi, ẹlẹgbẹ́ mi, àti ọ̀rẹ́ tí ó súnmọ́ mi, 14pẹ̀lú ẹni tí èmi ti jẹ ìgbádùn adùn ìdàpọ̀, bí a ṣe ń rìn pẹ̀lú àwùjọ ní ilé Ọlọ́run. 15Kí ikú kí ó dé bá wọn, kí wọn ó lọ láààyè sí isà òkú, jẹ́ kí wọn ó sọ̀kalẹ̀ sí ibojì pẹ̀lú ìpayà, nítorí tí ìwà búburú ń bẹ ní ibùjókòó wọn, àti nínú wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.