Saamu 5:9
Psalms 5:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́; ọkàn wọn kún fún ìparun. Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀; pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn.
Psalms 5:9 in English
Psalms 5:9 · Berean Standard Bible
For not a word they speak can be trusted; destruction lies within them. Their throats are open graves; their tongues practice deceit.*
Context
7Ṣùgbọ́n èmi, nípa títóbi àánú rẹ̀,
èmi yóò wá sínú ilé rẹ̀;
ní tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ ni èmi yóò tẹríba
sí ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ̀. 8Tọ́ mi, Olúwa, nínú òdodo rẹ,
nítorí àwọn ọ̀tá mi,
mú ọ̀nà rẹ tọ́ níwájú mi. 9Kò sí ọ̀rọ̀ kan ní ẹnu wọn tí a lè gbàgbọ́;
ọkàn wọn kún fún ìparun.
Ọ̀nà ọ̀fun wọn ni isà òkú tí ó ṣí sílẹ̀;
pẹ̀lú ahọ́n wọn ni wọ́n ń sọ ẹ̀tàn. 10Dá wọn lẹ́bi Ọlọ́run!
Jẹ́ kí rìkíṣí wọn jẹ́ ìṣubú wọn.
Lé wọn jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
nítorí wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ. 11Ṣùgbọ́n, jẹ́ kí gbogbo àwọn tí ó sádi ọ́ kí ó yọ̀;
jẹ kí wọn máa kọrin fún ayọ̀ títí.
Tan ààbò rẹ sórí wọn,
àti àwọn tí ó fẹ́ràn orúkọ rẹ yóò máa yọ̀ nínú rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.