Native Bible

Psalms 49:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn; ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò, jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀. Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́, isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn.

Psalms 49:14 in English

Psalms 49:14 · Berean Standard Bible

Like sheep they are destined for Sheol. Death will be their shepherd. The upright will rule them in the morning, and their form will decay in Sheol, far from their lofty abode.

Context

12Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́ ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé. 13Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó gbàgbọ́ nínú ara wọn, àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn, tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela. 14Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn; ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò, jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀. Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́, isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn. 15Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà kúrò nínú isà òkú, yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀. 16Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀. Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.