Saamu 49:11
Psalms 49:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé, ibùgbé wọn láti ìrandíran, wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.
Psalms 49:11 in English
Psalms 49:11 · Berean Standard Bible
Their graves * are their eternal homes— their dwellings for endless generations— even though their lands were their namesakes.
Context
9ní ti kí ó máa wà títí ayé
láìrí isà òkú. 10Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn. 11Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
ibùgbé wọn láti ìrandíran,
wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn. 12Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé. 13Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó
gbàgbọ́ nínú ara wọn,
àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn,
tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. Sela.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.