Saamu 48:9
Psalms 48:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run, àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
Psalms 48:9 in English
Psalms 48:9 · Berean Standard Bible
Within Your temple, O God, we contemplate Your loving devotion.
Context
7Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi Tarṣiṣi,
wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn. 8Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́,
bẹ́ẹ̀ ni àwa rí,
ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun
ní ìlú Ọlọ́run wa,
Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. Sela. 9Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run,
àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ. 10Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run,
ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé,
ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo. 11Jẹ́ kí òkè Sioni kí ó yọ̀
kí inú àwọn ọmọbìnrin Juda kí ó dùn
nítorí ìdájọ́ rẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.