Native Bible

Psalms 44:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa, ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká.

Psalms 44:13 in English

Psalms 44:13 · Berean Standard Bible

You have made us a reproach to our neighbors, a mockery and derision to those around us.

Context

11Ìwọ fi wá fún jíjẹ bí ẹran àgùntàn, Ìwọ sì ti tú wa ká sí àárín àwọn kèfèrí. 12Ìwọ ta àwọn ènìyàn rẹ fún owó kékeré, Ìwọ kò sì jẹ èrè kankan lórí iye tí ìwọ tà wọ́n. 13Ìwọ sọ wá di ẹni ẹ̀sín ní ọ̀dọ̀ àwọn aládùúgbò wa, ẹlẹ́yà àti ẹni àbùkù sí àwọn tí ó yí wa ká. 14Ìwọ ti sọ wá di ẹni ìfisọ̀rọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; àwọn ènìyàn ń mi orí wọn sí wa. 15Ìdójútì mi ń bẹ pẹ̀lú mi ní gbogbo ọjọ́, ìtìjú sì bojú mi mọ́lẹ̀,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.