Native Bible

Psalms 42:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀, àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi.

Psalms 42:8 in English

Psalms 42:8 · Berean Standard Bible

The LORD decrees His loving devotion by day, and at night His song is with me as a prayer to the God of my life.

Context

6Ọlọ́run mi, ọkàn mi ń rẹ̀wẹ̀sì nínú mi: nítorí náà, èmi ó rántí rẹ láti ilẹ̀ Jordani wá, láti Hermoni láti òkè Mibsari. 7Ibú omi ń pe ibú omi nípa híhó omi ṣíṣàn rẹ̀ gbogbo rírú omi àti bíbì omi rẹ̀ bò mí mọ́lẹ̀. 8Ní ọ̀sán ní Olúwa ran ìfẹ́ rẹ̀, àti ni àṣálẹ́ ni orin rẹ̀ wà pẹ̀lú mi àdúrà sí Ọlọ́run ayé mi. 9Èmi wí fún Ọlọ́run àpáta mi, “Èéṣe tí ìwọ fi gbàgbé mi? Èéṣe tí èmi o fi máa rìn nínú ìbànújẹ́, nítorí ìnilára ọ̀tá?” 10Bí ẹni pé idà egungun mi ni ẹ̀gàn tí àwọn ọ̀tá mi ń gàn mí, bí wọn ti ń béèrè ní gbogbo ọjọ́. “Níbo ni Ọlọ́run rẹ wà?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.