Saamu 38:19
Psalms 38:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì.
Psalms 38:19 in English
Psalms 38:19 · Berean Standard Bible
Many are my enemies without cause,* and many hate me without reason.*
Context
17Nítorí tí mo ti ṣetán láti ṣubú,
ìrora mi sì wà pẹ̀lú mi nígbà gbogbo. 18Mo jẹ́wọ́ ìrékọjá mi;
àánú sì ṣe mí fún ẹ̀ṣẹ̀ mi. 19Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìí pàtàkì, wọ́n lágbára púpọ̀,
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí ó kórìíra mi lọ́nà òdì. 20Àwọn tí wọn ń fi ibi san rere fún mi
àwọn ni ọ̀tá mi
nítorí pé mò ń tọ ìre lẹ́yìn. 21Má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀, ìwọ Olúwa!
Ọlọ́run mi, má ṣe jìnnà sí mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.