Native Bible

Psalms 37:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀, má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú.

Psalms 37:8 in English

Psalms 37:8 · Berean Standard Bible

Refrain from anger and abandon wrath; do not fret—it can only bring harm.

Context

6Yóò sì mú kí òdodo rẹ̀ jáde bí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀, àti ìdájọ́ rẹ̀ bí ọ̀sán gangan. 7Ìwọ dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Olúwa, kí o sì fi sùúrù dúró dè é; má ṣe ṣe ìkanra nítorí àwọn tí ń rí rere ní ọ̀nà wọn, nítorí ọkùnrin náà ti mú èrò búburú ṣẹ. 8Fàsẹ́yìn nínú inúbíbí, kí o sì kọ ìkáàánú sílẹ̀, má ṣe ṣe ìkanra, kí ó má ba à ṣé búburú pẹ̀lú. 9Nítorí tí á ó gé àwọn olùṣe búburú kúrò, ṣùgbọ́n àwọn tí ó bá dúró de Olúwa àwọn ni yóò jogún ilẹ̀ náà. 10Síbẹ̀ nígbà díẹ̀ sí i, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí mọ̀; nítòótọ́ ìwọ yóò fi ara balẹ̀ wo ipò rẹ̀, wọn kì yóò sí níbẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.