Saamu 37:28
Psalms 37:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́, kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀. Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
Psalms 37:28 in English
Psalms 37:28 · Berean Standard Bible
For the LORD loves justice and will not forsake His saints. They are preserved forever, but the offspring of the wicked will be cut off.
Context
26Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;
a sì máa bùsi i fún ni. 27Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;
nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé. 28Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,
kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.
Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,
ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò. 29Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé. 30Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.