Native Bible

Psalms 33:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa.

Psalms 33:5 in English

Psalms 33:5 · Berean Standard Bible

The LORD loves righteousness and justice; the earth is full of His loving devotion.

Context

3Ẹ kọ orin tuntun sí i; ẹ máa fi ọgbọọgbọ́n lu ohun èlò orin sí i, pẹ̀lú ariwo. 4Nítorí pé ọ̀rọ̀ Olúwa dúró ṣinṣin, gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ ni à ń ṣe nínú òtítọ́. 5Ó fẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; ilé ayé kún fún ìdúró ṣinṣin àti àánú Olúwa. 6Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ṣe dá àwọn ọ̀run, àti gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ogun wọn nípa ìmísí ẹnu rẹ̀. 7Ó kó àwọn omi òkun jọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó wà nínú ìgò; ó sì fi ibú ṣe ilé ìṣúra gbogbo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.