Saamu 32:8
Psalms 32:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ.
Psalms 32:8 in English
Psalms 32:8 · Berean Standard Bible
I will instruct you and teach you the way you should go; I will give you counsel and watch over you.
Context
6Nítorí náà jẹ́ kí gbogbo àwọn olódodo máa gbà àdúrà sí ọ
ní ìgbà tí a lè rí ọ;
nítòótọ́ nígbà tí ìṣàn omi ńlá bá ru sókè,
wọn kì yóò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. 7Ìwọ ni ibi ìpamọ́ mi;
ìwọ yóò pa mí mọ́ kúrò nínú ìyọnu;
ìwọ yóò fi orin ìgbàlà yí mi ka. Sela. 8Èmi yóò kọ́ ọ, èmi yóò sì fi ẹsẹ̀ rẹ lé ọ̀nà tí ìwọ yóò rìn
èmi yóò máa gbà ọ́ ní ìyànjú, èmi yóò sì máa fi ojú mi tọ́ ọ. 9Má ṣe dàbí ẹṣin tàbí ìbáaka,
tí kò ní òye
ẹnu ẹni tí a gbọdọ̀ fi ìjánu bọ̀,
kí wọn má ba à súnmọ́ ọ. 10Ọ̀pọ̀ ìkáàánú ní yóò wà fún ènìyàn búburú,
ṣùgbọ́n ìfẹ́ Olúwa tí ó dúró ṣinṣin
ni yóò yí àwọn tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa ká.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.