Native Bible

Psalms 31:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi.

Psalms 31:3 in English

Psalms 31:3 · Berean Standard Bible

For You are my rock and my fortress; lead me and guide me for the sake of Your name.

Context

1Nínú rẹ̀, Olúwa ni mo ti rí ààbò; má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí; gbà mí nínú òdodo rẹ. 2Tẹ́ etí rẹ sí mi, gbà mí kíákíá; jẹ́ àpáta ààbò mi, jẹ́ odi alágbára láti gbà mí. 3Ìwọ pàápàá ni àpáta àti ààbò mi, nítorí orúkọ rẹ, máa ṣe olùtọ́ mi, kí o sì ṣe amọ̀nà mi. 4Yọ mí jáde kúrò nínú àwọ̀n tí wọ́n dẹ pamọ́ fún mi, nítorí ìwọ ni ìsádi mi. 5Ní ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé; ìwọ ni o ti rà mí padà, Olúwa, Ọlọ́run òtítọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.