Saamu 30:5
Psalms 30:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀, ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé; ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́, ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀.
Psalms 30:5 in English
Psalms 30:5 · Berean Standard Bible
For His anger is fleeting, but His favor lasts a lifetime. Weeping may stay the night, but joy comes in the morning.
Context
3Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò. 4Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́. 5Nítorí pé ìbínú rẹ̀ wà fún ìgbà díẹ̀,
ojúrere rẹ̀ wà títí ayérayé;
ẹkún lè pẹ́ títí di alẹ́,
ṣùgbọ́n ayọ̀ yóò wá ní òwúrọ̀. 6Ní ìgbà ayé mi, mo wí pé,
“a kì yóò ṣí mi ní ipò padà.” 7Nípa ojúrere rẹ, Olúwa,
ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ bí òkè tí ó ní agbára;
ìwọ pa ojú rẹ mọ́,
àyà sì fò mí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.