Saamu 30:2
Psalms 30:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, ìwọ sì ti wò mí sàn.
Psalms 30:2 in English
Psalms 30:2 · Berean Standard Bible
O LORD my God, I cried to You for help, and You healed me.
Context
1Èmi yóò kókìkí i rẹ, Olúwa,
nítorí ìwọ ni ó gbé mi lékè
tí ìwọ kò sì jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi kí ó yọ̀ mí. 2Olúwa Ọlọ́run mi, èmi ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́,
ìwọ sì ti wò mí sàn. 3Olúwa, ìwọ ti yọ ọkàn mi jáde kúrò nínú isà òkú,
mú mi padà bọ̀ sípò alààyè kí èmi má ba à lọ sínú ihò. 4Kọ orin ìyìn sí Olúwa, ẹ̀yin olódodo;
kí ẹ sì fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.