Saamu 3:6
Psalms 3:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
Psalms 3:6 in English
Psalms 3:6 · Berean Standard Bible
I will not fear the myriads set against me on every side.
Context
4Olúwa ni mo kígbe sókè sí,
ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ rẹ̀ wá. Sela. 5Èmi dùbúlẹ̀, mo sì sùn;
mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró. 6Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹẹgbẹ̀rún ènìyàn
tí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká. 7Dìde, Olúwa!
Gbà mí, Ọlọ́run mi!
Lu gbogbo àwọn ọ̀tá mi ní àgbọ̀n;
kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú. 8Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.
Kí ìbùkún rẹ wà lórí àwọn ènìyàn rẹ. Sela.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.