Native Bible

Psalms 22:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ; ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó.

Psalms 22:3 in English

Psalms 22:3 · Berean Standard Bible

Yet You are holy, enthroned on the praises of Israel.

Context

1Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀? Èéṣe tí o fi jìnnà láti gbà mí là, àní sí igbe ìkérora mi? 2Ọlọ́run mi, ní ọ̀sán gangan ni mo kígbe, ṣùgbọ́n ìwọ kò dá mi ní ohùn: àti ní òru èmi kò dákẹ́. 3Ṣùgbọ́n síbẹ̀ ẹni mímọ́ ni Ìwọ; ẹni tí ó tẹ ìyìn Israẹli dó. 4Àwọn baba ńlá wa ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ; wọ́n ní ìgbẹ́kẹ̀lé, ìwọ sì gbà wọ́n. 5Ìwọ ni wọ́n sun ẹkún sí, wọ́n sì ní ìgbàlà; ìwọ ni wọ́n gbẹ́kẹ̀lé, a kò sì dójútì wọ́n.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.