Saamu 22:24
Psalms 22:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra ìpọ́njú àwọn tí a ni lára; kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é.
Psalms 22:24 in English
Psalms 22:24 · Berean Standard Bible
For He has not despised or detested the torment of the afflicted. He has not hidden His face from him, but has attended to his cry for help.
Context
22Èmi yóò kéde orúkọ rẹ láàrín arákùnrin àti arábìnrin mi;
nínú ìjọ ni èmi yóò máa yìn ọ́. 23Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ yìn ín!
Gbogbo ẹ̀yin ìran Jakọbu, ẹ fi ògo fún un!
Ẹ dìde fún un tẹ̀rù tẹ̀rù, ẹ̀yin irú-ọmọ Israẹli! 24Nítorí pé òun kò ṣátá, bẹ́ẹ̀ ni kò sì kórìíra
ìpọ́njú àwọn tí a ni lára;
kò sì fi ojú rẹ̀ pamọ́ fún mi
ṣùgbọ́n ó gbọ́ nígbà tí mo ké pè é. 25Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ìyìn mi yóò ti wá nínú àjọ ńlá;
ẹ̀jẹ́ rẹ̀ ni èmi yóò san níwájú àwọn tí o bẹ̀rù rẹ̀ 26tálákà yóò jẹ yóò sì yó;
àwọn tí n wá Olúwa yóò yin
jẹ́ kí ẹ̀mí rẹ̀ wà láààyè títí ayérayé!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.